Genesis 32:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N kò lẹ́tọ̀ọ́ sí èyí tí ó kéré jùlọ ninu ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀, ati òdodo tí o ti fihan èmi iranṣẹ rẹ, nítorí ọ̀pá lásán ni mo mú lọ́wọ́ nígbà tí mo gòkè odò Jọdani, ṣugbọn nisinsinyii, mo ti di ẹgbẹ́ ogun ńlá meji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi kò yẹ si kikini ninu gbogbo ãnu, ati ninu gbogbo otitọ, ti iwọ fihàn fun ọmọ-ọdọ rẹ, nitori pe, kìki ọpá mi ni mo fi kọja Jordani yi; nisisiyi emi si di ẹgbẹ meji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kò tilẹ̀ yẹ fún àánú àti òtítọ́ tí o ń fi hàn fún ìránṣẹ́ rẹ. Nítorí pé, kìkì ọ̀pá mi ni mo mu kúrò ni ilé kọjá Jọ́dánì yìí, ṣùgbọ́n nísin yìí, èmi ti di ẹgbẹ́ méjì.