Genesis 32:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sọ fún èyí tí ó ṣáájú patapata pé, “Nígbà tí Esau arakunrin mi bá pàdé rẹ, tí ó sì bi ọ́ pé, ‘Ti ta ni ìwọ í ṣe? Níbo ni ò ń lọ? Ta ló sì ni àwọn ẹran tí wọ́n wà níwájú rẹ?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si fi aṣẹ fun eyiti o tète ṣaju wipe, Nigbati Esau, arakunrin mi, ba pade rẹ, ti o si bi ọ wipe, Ti tani iwọ? nibo ni iwọ si nrè? ati ti tani wọnyi niwaju rẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó pàṣẹ fún èyí tí ó ṣáájú pé, “Nígbà tí arákùnrin mi Ísọ̀ bá pàdé rẹ tí ó sì béèrè ẹni tí ìwọ í ṣe àti ibi tí ìwọ ń lọ àti ẹni tí ó ni agbo ẹran tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ,