Genesis 32:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ẹ sì wí pé, ‘Jakọbu alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ” Nítorí ó rò ninu ara rẹ̀ pé, bóyá òun lè fi àwọn ẹ̀bùn tí ó tì ṣáájú wọnyi tù ú lójú, àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, nígbà tí ojú àwọn mejeeji bá pàdé, bóyá yóo dáríjì òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o wi pẹlu pe, Kiyesi i, Jakobu iranṣẹ rẹ mbọ̀ lẹhin wa. Nitori ti o wipe, Emi o fi ọrẹ ti o ṣaju mi tù u loju, lẹhin eyini emi o ri oju rẹ̀, bọya yio tẹwọgbà mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ rí i dájú wí pé, ẹ sọ fún-un pé, ‘Jákọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” Èrò Jákọ́bù ni láti fi àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tu Ísọ̀ lójú pé bóyá inú Ísọ̀ yóò dùn sí òun nígbà tí àwọn bá pàdé.