Genesis 32:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ọkunrin náà rí i pé òun kò lè dá Jakọbu, ó fi ọwọ́ kan kòtò itan rẹ̀, eegun itan Jakọbu bá yẹ̀ níbi tí ó ti ń bá a jìjàkadì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si ri pe on kò le dá a, o fọwọkàn a ni ihò egungun itan rẹ̀; ihò egungun itan Jakobu si yẹ̀ li orike, bi o ti mbá a jijakadi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jákọ́bù, ó fọwọ́ kan-án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ìké, bí ó ti ń ja ìjàkadì.