Genesis 32:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ ní mo ní àwọn mààlúù, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, agbo ẹran, àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin. Ẹ ní mo ní kí n kọ́ ranṣẹ láti sọ fún un ni, kí n lè rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ní malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agbo-ẹran, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin: mo si ranṣẹ wá wi fun oluwa mi, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo ní màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn àti ewúrẹ́. Mo tún ni àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin. Mo ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi kí èmi le è rí ojúrere rẹ.’ ”