Genesis 33:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí Jakọbu ti gbé ojú sókè, ó rí Esau tí ń bọ̀ pẹlu irinwo (400) ọkunrin. Ó bá pín àwọn ọmọ rẹ̀ fún Lea ati Rakẹli, ati àwọn iranṣẹbinrin mejeeji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
JAKOBU si gbé oju rẹ̀ soke, o si wò, si kiyesi i, Esau dé, ati irinwo ọkunrin pẹlu rẹ̀. On si pín awọn ọmọ fun Lea, ati fun Rakeli, ati fun awọn iranṣẹbinrin mejeji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jákọ́bù sì gbójú sókè, ó sì rí Ísọ̀ àti irinwó ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún Líà, Rákélì àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì.