Genesis 33:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Jakọbu dáhùn pé, “Rárá o, jọ̀wọ́, bí mo bá bá ojurere rẹ pàdé nítòótọ́ gba ẹ̀bùn tí mo mú wá lọ́wọ́ mi, nítorí pé rírí tí mo rí ojú rẹ tí inú rẹ sì yọ́ sí mi tó báyìí, ó dàbí ìgbà tí mo rí ojú Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jakobu si wipe, Bẹ̃kọ, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ nisisiyi, njẹ gbà ọrẹ mi lọwọ mi: nitori ti emi sa ri oju rẹ bi ẹnipe emi ri oju Ọlọrun, ti inu rẹ si dùn si mi;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jákọ́bù bẹ̀ ẹ́ wí pé, “Rárá bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ṣe pé, mo rí ojú rere rẹ, jọ̀wọ́ gba wọ́n lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe rí ojú rẹ̀ yìí, ó dàbí wí pé mo rí ojú Ọlọ́run ni báyìí, tí inú un rẹ̀ ti dùn sí mi.