Genesis 33:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Jakọbu dá a lóhùn, ó ní, “Ṣebí oluwa mi mọ̀ pé àwọn ọmọ kò lágbára tóbẹ́ẹ̀ ati pé mo níláti ro ti àwọn ẹran tí wọ́n ní ọmọ wẹ́wẹ́ lẹ́yìn, bí a bá dà wọ́n ní ìdàkudà ní ọjọ́ kan péré, gbogbo agbo ni yóo run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn on wi fun u pe, oluwa mi mọ̀ pe awọn ọmọ kò lera, ati awọn agbo-ẹran, ati ọwọ́-malu ati awọn ọmọ wọn wà pẹlu mi: bi enia ba si dà wọn li àdaju li ọjọ́ kan, gbogbo agbo ni yio kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Jákọ́bù wí fún un pé, “Ṣe ìwọ náà ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ wọ̀nyí kéré, àwọn màlúù àti àgùntàn pẹ̀lú sì ní àwọn ọmọ kéékèèké. Bí a bá dà wọ́n rìn jìnnà ju bí agbára wọn se mọ lọ, wọ́n lè kú.