Genesis 33:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Esau bá ní, “Jẹ́ kí n fi àwọn bíi mélòó kan sílẹ̀ pẹlu rẹ ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi.” Ṣugbọn Jakọbu dá a lóhùn pé, “Mo dúpẹ́, má wulẹ̀ ṣe ìyọnu kankan. Àní, kí n ṣá ti rí ojurere oluwa mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Esau si wipe, Njẹ ki emi ki o fi enia diẹ silẹ pẹlu rẹ ninu awọn enia ti o pẹlu mi. On si wipe, Nibo li eyini jasi, ki emi ki o sa ri õre-ọfẹ li oju oluwa mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ísọ̀ wí pé, “Jẹ́ kí n fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ nínú àwọn ọkùnrin mi nígbà náà.” Jákọ́bù wí pé, “Èéṣe, àní kí n sáà rí ojú rere olúwa mi?”