Genesis 33:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Esau gbé ojú sókè, tí ó rí àwọn obinrin ati àwọn ọmọ, ó ní, “Ta ni àwọn wọnyi tí wọ́n wà pẹlu rẹ?” Jakọbu dáhùn, ó ní, “Àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi ta èmi iranṣẹ rẹ lọ́rẹ ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri awọn obinrin ati awọn ọmọ; o si bi i pe, Tani wọnyi pẹlu rẹ? On si wipe, Awọn ọmọ ti Ọlọrun fi ore-ọfẹ fun iranṣẹ rẹ ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Ísọ̀ sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jákọ́bù, ó bèèrè lọ́wọ́ Jákọ́bù pé, “Ti tani àwọn wọ̀nyí?” Jákọ́bù sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.”