Genesis 33:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bá bèèrè, ó ní, “Kí ni o ti fẹ́ ṣe gbogbo àwọn agbo ẹran tí mo pàdé lọ́nà?” Jakọbu dáhùn, ó ní, “Mo ní kí n fi wọ́n wá ojurere Esau, oluwa mi ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Kini iwọ fi ọwọ́ ti mo pade ni pè? On si wipe, Lati fi ri ore-ọfẹ li oju oluwa mi ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ísọ̀ sì béèrè pé, “Kín ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ̀ tí mo pàdé wọ̀nyí?” Jákọ́bù dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.”