Genesis 34:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni a óo tó máa fi ọmọ wa fun yín tí àwa náà yóo máa fẹ́ ọmọ yín, a óo máa gbé pọ̀ pẹlu yín, a óo sì di ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li awa o fi awọn ọmọbinrin wa fun nyin, awa o si mú awọn ọmọbinrin nyin sọdọ wa; awa o si ma bá nyin gbé, awa o si di enia kanna.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwa yóò le máa fún yín ní ọmọ wa, tí àwa náà yóò máa fẹ́ ẹ yín. A ó máa gbé láàrin yín, a ó sì di ara kan pẹ̀lú yín.