Genesis 34:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ohun kan ṣoṣo ni wọ́n ní kí á ṣe kí á lè jọ máa gbé pọ̀, kí á sì di ọ̀kan, wọ́n ní olukuluku ọkunrin wa gbọdọ̀ kọlà abẹ́ gẹ́gẹ́ bíi tiwọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kìki ninu eyi li awọn ọkunrin na o ṣe jẹ fun wa, lati ma bá wa gbé, lati di enia kan, bi gbogbo ọkunrin inu wa ba kọlà, gẹgẹ bi nwọn ti kọlà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n kin ní kan ni a lè ṣe kí wọn tó gbà láti gbé pẹ̀lú wa, ìyẹn sì ni pé àwọn ọkùnrin wa yóò kọlà bí i tiwọn