Genesis 34:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ati gbogbo dúkìá wọn, àwọn ọmọ wọn ati àwọn aya wọn, gbogbo wọn ni wọ́n kó lẹ́rú, wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé wọn pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọrọ̀ wọn gbogbo, ati gbogbo ọmọ wọn wẹ́rẹ, ati aya wọn ni nwọn dì ni igbekun, nwọn si kó ohun gbogbo ti o wà ninu ile lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ọrọ̀ wọn, gbogbo obìnrin ìlú àti àwọn ọmọ wẹẹrẹ pátapáta ni wọ́n kó. Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé wọn bí ìkógun.