Genesis 34:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jakọbu sọ fún Simeoni ati Lefi pé, “Irú ìyọnu wo ni ẹ kó mi sí yìí? Ẹ sọ mí di ọ̀tá gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ yìí, láàrin àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. Àwa nìyí, a kò pọ̀ jù báyìí lọ. Tí wọ́n bá kó ara wọn jọ sí mi, wọn óo run mí tilé-tilé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jakobu si wi fun Simeoni on Lefi pe, Ẹnyin mu wahalà bá mi niti ẹnyin mu mi di õrun ninu awọn onilẹ, ninu awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi: bi emi kò si ti pọ̀ ni iye, nwọn o kó ara wọn jọ si mi, nwọn o si pa mi: a o si pa mi run, emi ati ile mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jákọ́bù wí fún Símónì àti Léfì wí pé, “Ẹ̀yin ti kó ìyọnu bá mi nípa sísọ mí di olóòórùn láàrin ará Kénánì àti Pérésì, tí ó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwa kò pọ̀, bí wọn bá wá parapọ̀ sígun sí wa, gbogbo wa pátapáta ni wọn yóò parun.”