Genesis 34:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ọmọ Jakọbu pada dé sílé, tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, inú bí wọn gidigidi nítorí bíbá tí Ṣekemu bá Dina lòpọ̀ pẹlu ipá yìí jẹ́ ìwà àbùkù gbáà ní Israẹli, irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò tọ́ sí ẹnikẹ́ni láti hù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Jakobu si ti oko dé nigbati nwọn gbọ́: inu awọn ọkunrin na si bàjẹ́, inu si ru wọn gidigidi, nitori ti o ṣe ohun buburu ni Israeli, niti o bá ọmọbinrin Jakobu dàpọ: ohun ti a ki ba ti ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Jákọ́bù sì ti oko dé, wọ́n sì gbọ́ ohun tí ó ṣelẹ̀ inú wọn sì bàjẹ́, ó sì ń bí wọn nínú gidigidi, nítorí pé, ohun àbùkù ńlá ni ó jẹ́ pé Ṣékémù bá ọmọ Jákọ́bù lò pọ̀-irú ohun tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá.