Genesis 35:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Israẹli ń gbé ibẹ̀, Reubẹni bá Biliha, aya baba rẹ̀ lòpọ̀, Jakọbu sì gbọ́ nípa rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe nigbati Israeli joko ni ilẹ na, Reubeni si wọle tọ̀ Bilha, àle baba rẹ̀ lọ; Israeli si gbọ́. Njẹ awọn ọmọ Jakobu jẹ́ mejila.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Ísírẹ́lì sì ń gbé ní ibẹ̀, Rúbẹ́nì wọlé tọ Bílíhà, àlè (ìyàwó tí a kò fi owó fẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀) baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lò pọ̀, Ísírẹ́lì sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Jákọ́bù sì bí ọmọkunrin méjìlá: