Genesis 35:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo wọn bá dá àwọn ère oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn jọ fún Jakọbu, ati gbogbo yẹtí tí ó wà ní etí wọn, Jakọbu bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ lábẹ́ igi oaku tí ó wà ní Ṣekemu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si fi gbogbo àjeji oriṣa ti o wà lọwọ wọn fun Jakobu, ati gbogbo oruka eti ti o wà li eti wọn: Jakobu si pa wọn mọ́ li abẹ igi oaku ti o wà leti Ṣekemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jákọ́bù ní gbogbo àjòjì òrìsà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jákọ́bù sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sabẹ́ igi Óákù ní Ṣékémù.