Genesis 35:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn. Jìnnìjìnnì láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sì dà bo gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká wọn, wọn kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si rìn lọ: ẹ̀ru Ọlọrun si mbẹ lara ilu ti o yi wọn ká, nwọn kò si lepa awọn ọmọ Jakobu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò wọn. Ìbẹ̀rù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì ń bá lé gbogbo ìlú tí wọ́n ń là kọjá ní ọ̀nà wọn tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹni tí ó le è dojú ìjà kọ wọ́n.