Genesis 36:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Sibeoni ni Aya ati Ana. Ana yìí ni ó rí àwọn ìsun omi gbígbóná láàrin aginjù, níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Sibeoni, baba rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi si li awọn ọmọ Sibeoni; ati Aja on Ana: eyi ni Ana ti o ri awọn isun omi gbigbona ni ijù, bi o ti mbọ́ awọn kẹtẹkẹtẹ Sibeoni baba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ṣíbéónì: Áíyà àti Ánà. Èyí ni Ánà tí ó rí ìṣun omi gbígbóná ní inú asálẹ̀ bí ó ti ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣébéónì baba rẹ̀.