Genesis 36:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó ṣe, Esau kó àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn mààlúù rẹ̀, àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ti kójọ ní ilẹ̀ Kenaani, ó kó kúrò ní ilẹ̀ Kenaani lọ́dọ̀ Jakọbu, arakunrin rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Esau si mú awọn aya rẹ̀, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn enia ile rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati gbogbo ohun-ọ̀sin, ati ohun iní gbogbo ti o ní ni ilẹ Kenaani; o si lọ si ilẹ kan kuro niwaju Jakobu arakunrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ísọ̀ sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kénánì, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jákọ́bù arakùnrin rẹ̀ wà.