Genesis 37:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àkọsílẹ̀ ìran Jakọbu nìyí: Josẹfu jẹ́ ọmọ ọdún mẹtadinlogun ó sì ń bá àwọn arakunrin rẹ̀ tọ́jú agbo ẹran ó wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Biliha ati àwọn ọmọ Silipa, àwọn aya baba rẹ̀. Josẹfu a sì máa sọ gbogbo àṣìṣe àwọn arakunrin rẹ̀ fún baba wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi ni iran Jakobu. Nigbati Josefu di ẹni ọdún mẹtadilogun, o nṣọ́ agbo-ẹran pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; ọmọde na si wà pẹlu awọn ọmọ Bilha, ati pẹlu awọn ọmọ Silpa, awọn aya baba rẹ̀; Josefu si mú ihin buburu wọn wá irò fun baba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni àwọn ìtàn Jákọ́bù. Nígbà tí Jósẹ́fù di ọmọ ọdún mẹ́tadínlógún (17), ó ń sọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwon ọmọ Bílíhà àti Sílípà aya baba rẹ̀ Jósẹ́fù sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn.