Genesis 37:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èmi pẹlu yín, a wà ní oko ní ọjọ́ kan, à ń di ìtí ọkà, mo rí i tí ìtí ọkà tèmi wà lóòró, ó dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì yí i ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún un.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sa wò o, awa nyí ití li oko, si wò o, ití mi dide, o si duro ṣanṣan; si wò o, ití ti nyin dide duro yiká, nwọn si ntẹriba fun ití mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sáà wò ó, àwa ń yí ìdì ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìdì ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìdì ọkà tiyín sì dòòyì yí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un.”