Genesis 37:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn arakunrin rẹ̀ bá bi í pé, “Ṣé o rò pé ìwọ ni yóo jọba lórí wa ni? Tabi o óo máa pàṣẹ lé wa lórí?” Wọ́n sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i nítorí àlá tí ó lá ati nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn arakunrin rẹ̀ si wi fun u pe, Iwọ o ha jọba lori wa bi? tabi iwọ o ṣe olori wa nitõtọ? nwọn si tun korira rẹ̀ si i nitori alá rẹ̀ ati nitori ọ̀rọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ ń gbérò àti jọba lé wa lórí bí? Tàbí ìwọ ó ṣe olórí wa ní tòótọ́?” Wọn sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i, nítorí àlá rẹ̀ àti nítorí ohun tí ó wí.