Genesis 37:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó tún lá àlá mìíràn, ó sì tún rọ́ ọ fún àwọn arakunrin rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbọ́, mo mà tún lá àlá mìíràn! Mo rí oòrùn, ati òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ mọkanla ní ojú àlá, gbogbo wọn foríbalẹ̀ fún mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si tun lá alá miran, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀, o wipe, Sa wò o, mo tun lá alá kan si i; si wò o, õrùn, ati oṣupa, ati irawọ mọkanla nforibalẹ fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, “Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń forí balẹ̀ fún mi.”