Genesis 38:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Juda bá sọ fún Tamari opó ọmọ rẹ̀ pé, “Wá pada sí ilé baba rẹ kí o lọ máa ṣe opó níbẹ̀ títí tí Ṣela, ọmọ mi yóo fi dàgbà.” Ṣugbọn ọ̀rọ̀ tí Juda sọ yìí kò dé inú rẹ̀ nítorí ẹ̀rù ń bà á pé kí Ṣela náà má kú bí àwọn arakunrin rẹ̀, Tamari bá pada lọ sí ilé baba rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Judah wi fun Tamari aya ọmọ rẹ̀ pe, Joko li opó ni ile baba rẹ, titi Ṣela ọmọ mi o fi dàgba: nitori o wipe, Ki on má ba kú pẹlu, bi awọn arakunrin rẹ̀. Tamari si lọ, o si joko ni ile baba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Júdà wí fún Támárì, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Lọ máa gbé bí opó ní ilé baba rẹ, títí tí Ṣélà yóò fi dàgbà ó lérò pé òun náà lè kú bí àwọn arákùnrin rẹ̀ tó kù.” Nígbà náà ni Támárì ń lọ gbé ilé baba rẹ̀.