Genesis 38:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya Juda, tíí ṣe ọmọ Ṣua kú. Nígbà tí Juda ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, òun ati Hira ará Adulamu, ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá múra, wọ́n lọ sí Timna lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń rẹ́ irun aguntan Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ọjọ́ si npẹ́, ọmọbinrin Ṣua, aya Juda kú; Judah si gbipẹ̀, o si tọ̀ awọn olurẹrun agutan rẹ̀, lọ si Timnati, on ati Hira ọ̀rẹ́ rẹ̀, ara Adullamu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Júdà, ọmọbìnrin Súà sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Júdà sì pé, ó gòkè lọ sí Tímínà, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hírà ará Ádúlámù tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ.