Genesis 38:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Juda dáhùn, ó ní, “N óo fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ kan ranṣẹ sí ọ láti inú agbo ẹran mi.” Tamari ní, “O níláti fi nǹkankan dógò títí tí o óo fi fi ọmọ ewúrẹ́ náà ranṣẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, emi o rán ọmọ ewurẹ kan si ọ lati inu agbo wá. On si wipe, iwọ ki o fi ògo fun mi titi iwọ o fi rán a wá?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọ ewúrẹ́ kan ránṣẹ sí ọ láti inú agbo ẹran.” Obìnrin náà sì dáhùn pé, “Ṣé ìwọ yóò fún mi ní ohun kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí tí ìwọ yóò fi fi ránṣẹ́?”