Genesis 38:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Juda bá bèèrè pé kí ni ó fẹ́ kí òun fi dógò. Ó dá a lóhùn, ó ní, “Èdìdì rẹ pẹlu okùn rẹ, ati ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ.” Juda bá kó wọn fún un, ó sì bá a lòpọ̀, Tamari sì lóyún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si bi i pe, Ògo kili emi o fi fun ọ? on si wipe, Èdidi rẹ, ati okùn rẹ, ati ọpá rẹ ti o wà li ọwọ́ rẹ; o si fi wọn fun u, o si wọle tọ̀ ọ lọ, on si ti ipa ọdọ rẹ̀ yún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Júdà sì bi í pé, “Ẹ̀rí wo ni kí n fún ọ?” Ó sì dáhùn pé, “Èdìdì ìdámọ̀ okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ rẹ ti ń bẹ ní ọwọ́ rẹ.” Ó sì kó wọn fún un, ó sì sùn tì í, obìnrin náà sì lóyún nípaṣẹ̀ rẹ̀.