Genesis 38:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bi àwọn ọkunrin kan, ará ìlú náà pé, “Níbo ni obinrin aṣẹ́wó tí ó máa ń jókòó ní gbangba lẹ́bàá ọ̀nà Enaimu yìí wà?” Wọ́n dáhùn pé, “Kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan ní àdúgbò yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li o bère lọwọ awọn ọkunrin ibẹ̀ na pe, Nibo ni panṣaga nì ngbé, ti o wà ni Enaimu li ẹba ọ̀na? Nwọn si wipe, Panṣaga kan kò sí nihin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àdúgbò náà pé, “Níbo ni aṣẹ́wó (aṣẹ́wó ibi ojúbọ òrìṣa) tí ó wà ní etí ọ̀nà Énáímù wà?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kò sí aṣẹ́wó kankan níbí”