Genesis 38:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn bí oṣù mẹta sí i, ẹnìkan wá sọ fún Juda pé, “Wò ó! Iṣẹ́ aṣẹ́wó ni Tamari, opó ọmọ rẹ ń ṣe, ó sì ti lóyún.” Juda bá dáhùn, ó ní, “Ẹ lọ mú un wá kí wọ́n dáná sun ún.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe niwọ̀n oṣù mẹta lẹhin rẹ̀, ni a wi fun Judah pe, Tamari aya ọmọ rẹ ṣe àgbere; si kiyesi i pẹlu, o fi àgbere loyun. Judah si wipe, Mú u jade wá, ki a si dána sun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, wọn sọ fún Júdà pé, “Támárì aya ọmọ rẹ̀ ṣe àgbèrè, ó sì ti lóyún.” Júdà sì wí pé, “Ẹ mú un jáde, kí ẹ sì dá iná sun ún.”