Genesis 38:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n mú un dé, ó ranṣẹ sí baba ọkọ rẹ̀, ó ní, “Ẹni tí ó ni àwọn nǹkan wọnyi ni ó fún mi lóyún. Jọ̀wọ́ yẹ̀ wọ́n wò, kí o mọ ẹni tí ó ni èdìdì yìí pẹlu okùn rẹ̀, ati ọ̀pá yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati a si mú u jade, o ranṣẹ si baba ọkọ rẹ̀ pe, ọkunrin ti o ní nkan wọnyi li emi yún fun: o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mọ̀ wọn, ti tani nkan wọnyi, èdidi, ati okùn, ati ọpá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n sì ti ń mú un jáde, ó ránṣẹ́ sí baba ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó fún mi lóyún. Wò ó, bóyá o lè mọ ẹni tí ó ni èdìdì ìdámọ̀, okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọ̀nyí.”