Genesis 38:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ó ti ń rọbí, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ náà yọ ọwọ́ jáde, ẹni tí ń bá a gbẹ̀bí bá so òwú pupa mọ́ ọn lọ́wọ́, ó ní “Èyí tí ó kọ́ jáde nìyí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe nigbati o nrọbí, ti ọkan yọ ọwọ́ jade: iyãgba si mú okùn ododó o so mọ́ ọ li ọwọ́, o wipe, Eyi li o kọ jade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó sì ti ń bímọ, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà na ọwọ́ jáde; agbẹ̀bí sì so okùn òdòdó mọ́ ọmọ náà ní ọrùn ọwọ́. Ó sì wí pé, “Èyí ni o kọ́kọ́ jáde.”