Genesis 38:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ọmọ náà ti fa ọwọ́ rẹ̀ pada, arakunrin rẹ̀ bá jáde. Agbẹ̀bí náà bá wí pé, “Ṣé bí o ti fẹ́ rìn nìyí, ó hàn lára rẹ.” Ó bá sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, bi o ti fà ọwọ́ rẹ̀ pada, si kiyesi i, aburo rẹ̀ jade: o si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yà? yiyà yi wà li ara rẹ, nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Peresi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nìgbá tí ó fa ọwọ́ rẹ̀ padà, èkejì rẹ̀ jáde. Támárì sì wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Pérésì.