Genesis 38:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Onani mọ̀ pé ọmọ tí opó náà bá bí kò ní jẹ́ ti òun, nítorí náà, nígbàkúùgbà tí ó bá ń bá opó yìí lòpọ̀, yóo sì da nǹkan ọkunrin rẹ̀ sílẹ̀, kí ó má baà bí ọmọ tí yóo rọ́pò arakunrin rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Onani si mọ̀ pe, irú-ọmọ ki yio ṣe tirẹ̀; o si ṣe bi o ti wọle tọ̀ aya arakunrin rẹ̀ lọ, o si dà a silẹ, ki o má ba fi irú-ọmọ fun arakunrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Ónání mọ̀ pé àwọn ọmọ náà kì yóò jẹ́ ti òun, nítorí náà ni gbogbo ìgbà tí ó bá wọlé tọ aya arákùnrin rẹ̀ lọ, ilẹ̀ ni ó ń da nǹkan ọkùnrin rẹ̀ sí, kí ó má bá a bímọ fún arákùnrin rẹ̀.