Genesis 39:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Iṣimaeli mú Josẹfu lọ sí Ijipti, wọ́n sì tà á fún Pọtifari ará Ijipti. Pọtifari yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè Farao, òun sì tún ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A SI mú Josefu sọkalẹ wá si Egipti; Potifari, ijoye Farao kan, olori ẹṣọ́, ara Egipti, si rà a lọwọ awọn ara Iṣmaeli ti o mú u sọkalẹ wá sibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n mú Jósẹ́fù dé Éjíbítì, Pótífà, ará Éjíbítì tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Fáráò. Òun ni olórí àwọn ọmọ ogun Fáráò. Ó ra Jósẹ́fù lọ́wọ́ àwọn ará Íṣímáẹ́lì tí wọ́n mú-un lọ ṣíbẹ̀.