Genesis 39:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Pọtifari ti fi Josẹfu ṣe alabojuto ilé rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí bukun ìdílé Pọtifari, ará Ijipti náà, ati ohun gbogbo tí ó ní nítorí ti Josẹfu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe lati ìgba ti o ti fi Josefu jẹ́ olori ile rẹ̀, ati olori ohun gbogbo ti o ní, ni OLUWA busi ile ara Egipti na nitori Josefu: ibukún OLUWA si wà lara ohun gbogbo ti o ní ni ile ati li oko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ìgbà tí ó ti fi Jósẹ́fù jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun-ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún-un nítorí Jósẹ́fù. Ìbùkún OLÚWA wà lórí gbogbo ohun tí Pọ́tífà ní, nílé àti lóko.