Genesis 39:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, ó fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ Josẹfu níwọ̀n ìgbà tí ó wà pẹlu rẹ̀, kò sì bìkítà fún ohunkohun mọ́, àfi oúnjẹ tí ó ń jẹ. Josẹfu ṣígbọnlẹ̀, ó sì lẹ́wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si fi ohun gbogbo ti o ní si ọwọ́ Josefu; kò si mọ̀ ohun ti on ní bikoṣe onjẹ ti o njẹ. Josefu si ṣe ẹni daradara ati arẹwà enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì fi Jósẹ́fù ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Jósẹ́fù ṣe àkóṣo ilé e rẹ̀. Josẹ́fù sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀,