Genesis 4:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn OLUWA dáhùn, ó ní, “Rárá o! ẹnikẹ́ni tí ó bá pa Kaini, a óo gbẹ̀san lára rẹ̀ nígbà meje.” Nítorí náà OLUWA fi àmì sí ara Kaini kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí i má baà pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun u pe, Nitorina ẹnikẹni ti o ba pa Kaini a o gbẹsan lara rẹ̀ lẹrinmeje. OLUWA si sàmi si Kaini lara, nitori ẹniti o ba ri i ki o má ba pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n, OLÚWA wí fún pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ẹnikẹ́ni bá pa Káínì, èmi yóò gbẹ̀san ní ara onítọ̀hún ní ìgbà méje.” Nígbà náà ni Ọlọ́run fi àmì sí ara Káínì, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí má ba pa á.