Genesis 41:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn mààlúù meje mìíràn tún jáde láti inú odò náà, gbogbo wọn rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, n kò rí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o joro, ti o burujù ni wiwò, ti o si rù, jade soke lẹhin wọn, nwọn buru tobẹ̃ ti emi kò ri irú wọn rí ni ilẹ Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógo, wọn kò sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí n kò tíì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Éjíbítì.