Genesis 41:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó rí àwọn mààlúù meje kan tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀, tí ara wọ́n sì ń dán, wọ́n ti inú odò náà jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko létí odò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i abo-malu meje, ti o dara ni wiwò, ti o sanra, jade lati inu odò na wá: nwọn si njẹ ninu ẽsu-odò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko.