Genesis 41:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Rírí tí yóo tún rí, ó rí àwọn mààlúù meje mìíràn, wọ́n tún ti inú odò náà jáde wá, àwọn wọnyi rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, wọ́n dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn meje ti àkọ́kọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o buru ni wiwò, ti o si rù, jade lẹhin wọn lati inu odò na wá; nwọn si duro tì awọn abo-malu nì ni bèbe odò na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Náílì, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà.