Genesis 41:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ṣugbọn lẹ́yìn náà ìyàn yóo mú fún ọdún meje, ìyàn náà yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọdún meje tí oúnjẹ pọ̀ yóo di ìgbàgbé ní ilẹ̀ Ijipti, ìyàn náà yóo run ilẹ̀ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin wọn ọdún meje ìyan si mbọ̀; gbogbo ọ̀pọ nì li a o si gbagbe ni ilẹ Egipti; ìyan na yio si run ilẹ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú yóò tẹ̀lé e, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé pé ọdún méje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà yanturu tilẹ̀ ti wà rí, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà,