Genesis 41:45 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà ó sọ Josẹfu ní orúkọ Ijipti kan, orúkọ náà ni Safenati Panea, ó sì fi Asenati, ọmọ Pọtifera, fún un láti fi ṣe aya. Pọtifera yìí jẹ́ babalóòṣà oriṣa Oni, ní ìlú Heliopolisi. Josẹfu sì lọ káàkiri ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Farao si sọ orukọ Josefu ni Safnati-paanea; o si fi Asenati fun u li aya, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si jade lọ si ori ilẹ Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fáráò sì sọ Jósẹ́fù ní orúkọ yìí: Ṣefunati-Páníà èyí tí ó túmọ̀ sí, (ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà), Ó sì fun un ní Áṣénátì ọmọ Pótífẹ́rà, alábojútó òrìṣà Ónì, gẹ́gẹ́ bí aya. Jósẹ́fù sì rin gbogbo ilẹ̀ náà já.