Genesis 41:48 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Josẹfu bẹ̀rẹ̀ sí kó oúnjẹ jọ fún ọdún meje tí oúnjẹ fi pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ Ijipti, ó ń pa wọ́n mọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n bá rí kójọ ní agbègbè ìlú ńlá kọ̀ọ̀kan, Josẹfu a kó o pamọ́ sinu ìlú ńlá náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si kó gbogbo onjẹ ọdún meje nì jọ, ti o wà ni ilẹ Egipti, o si fi onjẹ na ṣura ni ilu wọnni: onjẹ oko ilu ti o yi i ká, on li o kójọ sinu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóṣẹ́fù kó gbogbo oúnjẹ tí a pèṣè ni ilẹ̀ Éjíbítì ní ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, ó sì pa wọ́n mọ́ sí àwọn ìlú. Ní ìlú kọ̀ọ̀kan ni ó kó gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbìn ní àyíká ìlú wọn sí.