Genesis 41:55 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí oúnjẹ kò sí mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, àwọn eniyan náà kígbe tọ Farao lọ fún oúnjẹ. Farao sọ fún gbogbo wọn pé, “Ẹ tọ Josẹfu lọ, ohunkohun tí ó bá wí fun yín ni kí ẹ ṣe.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ìyan mú ni gbogbo ilẹ Egipti, awọn enia kigbe onjẹ tọ̀ Farao: Farao si wi fun gbogbo awọn ara Egipti pe, Ẹ ma tọ̀ Josefu lọ; ohunkohun ti o ba wi fun nyin ki ẹ ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ará Éjíbítì bẹ̀rẹ̀ sí ní rí ipá ìyàn náà, wọ́n kígbe sí Fáráò. Nígbà náà ni Fáráò wí fún wọn pé, “Ẹ lọ bá Jóṣẹ́fù, ẹ ṣe ohun tí ó bá wí fún un yín.”