Genesis 41:57 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ayé ni ó sì ń wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní Ijipti tí wọ́n wá ra oúnjẹ, nítorí pé ìyàn náà mú gidigidi ní gbogbo ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ilẹ gbogbo li o si wá si Egipti lati rà onjẹ lọdọ Josefu; nitori ti ìyan na mú gidigidi ni ilẹ gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè sì ń wá láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Jósẹ́fù, nítorí ìyàn náà pọ̀ gidigidi káàkiri gbogbo ayé.