Genesis 42:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ rán ọ̀kan ninu yín kí ó lọ mú àbíkẹ́yìn yín wá, ẹ̀yin yòókù ẹ óo wà ninu ẹ̀wọ̀n títí a óo fi mọ̀ bóyá òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mo tún fi orúkọ Farao búra, amí ni yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ rán ẹnikan ninu nyin, ki o si mú arakunrin nyin wá, a o si pa nyin mọ́ ninu túbu, ki a le ridi ọ̀rọ nyin, bi otitọ wà ninu nyin: bikoṣe bẹ̃, ẹmi Farao bi amí ki ẹnyin iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ rán ọ̀kan nínú yín lọ láti mú arákùnrin yín wá, àwa yóò fi ẹ̀yin tókù pamọ́ sínú àtìmọ́lé, kí àwa ba à lè mọ bóyá òtítọ́ ni ẹ̀yin ń wí. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé irọ́ ni ẹ̀yin ń pa, ní òtítọ́ bí Fáráò ti ń bẹ láàyè ayọ́lẹ̀wò ni yín!”