Genesis 42:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ̀rọ̀ pé, “Dájúdájú, a jẹ̀bi arakunrin wa, nítorí pé a rí ìdààmú ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá, ṣugbọn a kò dá a lóhùn, ohun tí ó fà á nìyí tí ìdààmú yìí fi dé bá wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun ara wọn pe, Awa jẹbi nitõtọ nipa ti arakunrin wa, niti pe, a ri àrokan ọkàn rẹ̀, nigbati o bẹ̀ wa, awa kò si fẹ́ igbọ́; nitorina ni iyọnu yi ṣe bá wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ń sọ ọ́ láàrin ara wọn wí pé, “Dájúdájú a ń jìyà nítorí ohun tí a ṣe sí Jósẹ́fù. A rí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbẹ́bẹ̀, nítorí náà ni ìdààmú yìí fi dé bá wa.”