Genesis 42:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Reubẹni bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Mo sọ fun yín àbí n kò sọ, pé kí ẹ má fi ohunkohun ṣe ọmọ náà? Ṣugbọn ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́, òun nìyí nisinsinyii, ẹ̀san ni ó dé yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Reubeni si da wọn li ohùn pe, Emi kò wi fun nyin pe, Ẹ máṣe ṣẹ̀ si ọmọde na; ẹ kò si fẹ̀ igbọ́? si wò o, nisisiyi, a mbère ẹ̀jẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Rúbẹ́nì fèsì pé, “Ǹjẹ́ ń ò wí fún yín pé kí ẹ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ọmọdé-kùnrin náà? Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́! Nisinsin yìí a ń béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ wa.”